Home orisiirisii Mo si maa se igbeyawo – Rita Dominic
orisiirisii - November 13, 2018

Mo si maa se igbeyawo – Rita Dominic

Osere Nollywood, Rita Dominic, ti so pe oun si maa se igbeyawo lojo kan.
Rita Dominic ti pe eni odun metalelogoji (43 years), to si je okan lara awon ilumomika alariya ti ko tii se igbeyawo.
O ni sugbon kii se pe tori oun ti awon eniyan maa n so nipa awon ti ko tii lade ori ni oun se fe gbe igbese naa. O ni nitori ara oun, bo se wu oun lokan ni.
Rita Dominic ni eniyan ko gbodo maa se nnkan nitori ohun ti awon eniyan kan tabi ara ilu ba n so.
O ni o dara ki eniyan maa gbe igbese ti o ba ni igbagbo ninu ni, tori kii se gbogbo igba ni oro opo eniyan maa n je otito.
Osere naa so eyi lasiko to n dahun awon ibeere kan lori eto kan ni telifisan TVC.
O ni nigba kan, die lo ku ki oun se igbeyawo, sugbon oun sun seyin nigba ti oun ri awon apere kan.
Rita Dominic wa lara awon osere nla nla ti won ko si nile oko.
Lara won ni Genevieve Nnaji, Dayo Amusa, Ini Edo ati Mercy Aigbe.
Sugbon Edo ati Aigbe ti se igbeyawo tele, ti nnkan si daru nigba to ya.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…