Home Orisirisi Oju Aafaa ati Noosi to n ta ibi omo ni Ilorin
Orisirisi - November 11, 2018

Oju Aafaa ati Noosi to n ta ibi omo ni Ilorin

Ojo gbogbo ni t’ole, ojo kan ni ti olohun, eyi lo difa fun aafaa to ra ibi omo olomo ni egberun lona ogun naira lowo noosi.

Arabinrin Fatima Sulaiman ni noosi ile iwosan Capstone ni opopona Taiwo ni ilu Ilorin to je ore timotimo iyawo aafaa Salaudeen Ibrahim. Iyawo yii ni oko re ran pe ki o ba oun so fun ore re pe oun nilo ibi omo fun adura kan.

Leyin osu kan ni noosi Fatima to ri ibi omo kan fi ranse si aafaa bi o tile je pe o ni oun ko tii tewo gba owo ibi omo naa ti owo awon agbofinro fi te oun.

Ni igba ti owo te aafaa naa, o ni igba akoko niyi ti oun maa fe dan oogun owo ti oun jogun wo.

Oga olopaa ipinle naa, ogbeni Bolaji Fafowora ni awon mejeeji lo ti jewo ni ago awon, won si maa foju ba ile-ejo laipe.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Nàìjíríà sì nílò Ọbásanjọ́ fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí- Buhari

Nàìjíríà sì nílò Ọbásanjọ́ fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí- Buhari Fẹ́…