Home Orisirisi Awon osise wo ese sokoto kan naa pelu ijoba
Orisirisi - November 11, 2018

Awon osise wo ese sokoto kan naa pelu ijoba

Orisiirisii ipade ni o ti n waye laarin ijoba apapo ati awon osise orileede Naijiria. Ajo osise ni awon ti fun ijoba apapo ni aaye to lati le mo odo ti won maa da orunla si.

Leyin opolopo ipade ni ijoba apapo ni agbara ijoba ko gbe ju egberun merinlelogun lo nigba ti awon ijoba ipinle ni ti awon ko le ji egberun mejilelogun ati aabo lo.

Ajo osise ni ko si ohun to jo eleyii nitori pe awon ko toro bara. Awon fe gba owo oogun awon ni. Won ni owo awon ko gbodo din ni egberin lona ogbon naira fun osise ti owo re kere ju.

Omowe Chris Ngige ni agbara ijoba ko le ka iye owo ti won n beere yi, o ni ki awon naa wo bi ilu se ri ki won je ki awon jo fara daa.

Ajo osise ni iyanse-lodi to lagbara maa bere ni ojo kefa osu kokanla odun yii. Won ni yiyan ise lodi naa maa lo ni ara oto nitori pe awon ko ni je ki awon ileese aladaani gan-an lo si enu ise won titi ti ijoba fi maa da awon lohun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…