Home ÀRÒJINLẸ̀ Olè ni àwọn báǹkì wa
ÀRÒJINLẸ̀ - November 9, 2018

Olè ni àwọn báǹkì wa

Yoruba bo, won ni “aafaa to ni iyan yoo mu, omo tire naa ko ni je tira”. Oro Naijiria n fe amojuto kiakia, ilu yii ti le de bi wi pe onikaluku kan n fi iya je awon ara ilu bi o se wu won.
Ijoba apapo ni lati gba ijoba re pada. Ko dara ki won fi eniyan joye awodi ki o ma le gbe adiye. Ijoba o gbodo ko eti ikun si ohun to n sele labala eto eko, labala eto ilera, eto ogbin, aabo ilu ati bee bee lo.
Ijoba nikan lo lagbara lati se ohun ti opo olowo ilu tabi alagbara ilu ko le se lai ta eje sile. Ijoba gbodo wa loke gbogbo nnkan. Ti a ko ba ni paro fun ara wa, aisedede po kaakiri ilu yii ti onikaluku kan n se ohun to wuu.
Ojo ti pe ti a ti n pariwo ole jija awon ile ifowopamo wa gbogbo. Orisirisii ona ni won si fi n gba je ara ilu niya. Eyi tun je ki awon ara ilu maa kabamo pe awon ko ba ti mo ki awon maa gbele ko owo awon si tabi ki awon maa koo si abe ibusun ati bee bee lo.
Ni aye igbakan, ti a ba fowo si banki, o maa n le sii ni eyi to wa lara idi pataki ti a fi n fi owo si ile ifowo-pamo-si. Lasiko ti ko si amojuto kankan fun won mo bayii, owo kan n din sii lojoojumo ni. Awon ni won maa ki onibara ku ojo ibi re ti won tun maa yowo olojo-ibi, won n yowo ikinni fun odun Ileya, odun Keresi, odun tuntun, odun aawe, odun Ajinde, odun tuntun, won n yowo atejise iye owo onibara ni iseju-iseju, won n yowo amojuto owo onibara, won n yowo sitambu ti won n lo, won n yowo biro ti won n lo, won n yowo o to ojo meta ti a ti ri onibara keyin ati bee lo.
Eyi to n dun awa ara ilu ju ni ki eniyan fe ra kaadi lori aago re ki won yo owo ki won ma fi kaadi ranse. Ti e ba si lo si ofiisi won, won a ni ki e towo bo iwe ki e si ko deeti ati iye owo naa sile, ki e maa reti owo naa ni akanti yin laipe, iro paraku ma ni eleyii. Opo owo bee ni o maa n wo igbo atuu. Opo eniyan ni ko ki n ri aaye maa paara awon banki yii nitori ki epe ma baa po ju ohun to nu lo. Iwa ole ojukoroju yii buru pupo nitori gbogbo wa naa ni a jo n pariwo pe ole ni awon oloselu kan nigba ti awa kan je adigunjale. Ijoba ni lati gba ara ilu sile. Arojinle tun di ose to n bo lase Edumare.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…