LÁGBO ÀRÍYÁ - orisiirisii - November 9, 2018

Oga Bello, Funsho Adeolu, Dayo Amusa, àti àwọn míràn jẹ jáde nínú eré oní-tẹ̀léńtẹ̀lé tuntun

Àgbà-ọ́jẹ̀ òṣèré, Adebayo Salami tí gbogbo ayé mọ̀ sí Ọ̀gá Bellò, ti ṣe àṣepárí eré Yorùbá oní-tẹ̀léńtẹ̀lé alábala mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ ‘Alágbára’, tí wọ́n ṣe ní pàtàkì fún ile-iṣẹ́ amóhùnmáwòrán tó tayọ jù , StarTimes.

Ìròyìn fi tóni létí pé eré oní-tẹ̀léńtẹ̀lé yìí ń la àsekágbá iṣẹ́ tí yóò mú kí ó gbìnàyá ju àwọn yókù lọ tó bá jáde.

Ọ̀gá Bellò ṣe àfihàn pé pípawọ́pọ̀ pẹ̀lú StarTimes lórí àkànṣe iṣẹ́ yìí wáyé nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ìgbélárugẹ àṣà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nípa kíkọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú eré tí yó fọwọ́ kan gbogbo agbọn ayé àti àwùjọ.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ‘Alágbára’ jẹ́ eré tí a fi ọpọlọ gbé kalẹ̀ tí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé àwọn onírúurú ọkùnrin àti ipa tí àwọn obìnrin tó wà nínú ayé e wọn ń kó.

Àwọn àgbà òṣèré míràn tó wà nínú eré náà ni Rónkẹ́ Oshòdì Òkè, Tóyìn Adégbọlá, Yẹmí Ṣóladé, Fẹ́mi Adébáyọ̀, Ṣótáyọ̀, Délé Odùlé, Bukky Arugbá àti àwọn míràn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…