Home Orisirisi N22, 500 losu je 700 naira lojumo: Buruku iya n je osise Naijiria
Orisirisi - November 5, 2018

N22, 500 losu je 700 naira lojumo: Buruku iya n je osise Naijiria

N22, 500 losu je 700 naira lojumo: Buruku iya n je osise Naijiria

Ti a ba ni ka so otito, iya nla lo n je osise Naijiria. Leyin pe oro aje yan won je, ilana isejoba ni Naijiria n fiya je won.
Owo ti opo ijoba ati ile ise n san fun awon osise kere ju.
Bakan naa, opo won ni ko tun n ri owo osu gba lasiko to ye.
Eyi n sele ni opo awon ile ise aladani, to si n sele nile ise ijoiba naa.
Nigba ti ijoba ba n je osise lowo, bawo lo se fe lenu lati pe awon onise adani to n se bee nija?
Igba ti babalawo ba n sunkun ori fifo, kin la fe ki alaisan o se?
Ni awon orile-ede tori won pe gidi, ti won si nifee osise lokan, ko seni to lori laya lati je osise lowo.
Ile ise aladani tio ba dan iru re lasa, ijoba yoo ti pa a ni, ti won si le ta a lati san gbese to ba je.
Iru ironu yii lo wa si IROYIN OWURO lokan nipa idunadura ti egbe awon osise – Nigerian Labour Congress – n se pelu ijoba ati awon egbe oludasesile miran.
Lati odun 2010 ni ijoba ti fi kun owo osu osise lona to gunmo, nigba ti ijoba Goodluck Jonathan gbe owo osu osise to kere ju si N18,000.
Bi a ba wo o daadaa, N18, 000 losu tumo si N600 lojumo.
Ti a bay o owo moto nibe, ti a yowo ounje eemeta fun osise naa lojumo, ko si nnkan kan nile mo fun oro ilera, ko si owo Kankan fun ounje iyawo ati omo re, ko si si kobo fun owo ile iwe won.
Lati igba naa, nnkan ti n kan ni Naijiria, ojo ni ko ro.
Owongogo oja, afikun owo ile iwe ati, ni pataki afikun owo epo betiro ati disu ti so owo ti osise n gba di yeye.
Idi niyi ti awon osise fi fi aake kori bayii, ti won n beere fun ekunwo.
Lati nnkan bii egberun lona ogota naira ti won n ja fun tele, won ti wale si egberun lona ogbon – N30,00.
Ijoba Apapo setan lati san eyi, sugbon awon ijioba ipinle ni ko si ewe ti awon yoo fi po on.
Bakan naa ni awon onise adani ko fe ki ijoba gbe ajaga ti kii se tawon le awon lorun.
Awon gomina ni egberun lona ogun ati meji – N22,000 – ni apa awon kan, eyi ti awon NLC ni ere omode ni won n se.
Oro naa ti wa pakoso bayii, latari bi NLC se ni awon fe da ise sile, ti ijoba si ti gba ase ni kootu pe won ko gbodo se beee.
Bi o tile je pe awon osise naa si n leri pe awon ni eto lati fi ilodi sise han, oniya ni yoo je eyi to po ni oro Naijiria je.
Orile-ede yii n re awon eniyan re je poupo.
Ibiu ti ijoba ti ni oun ko ti le san N30,000 losu, awon logaa-logaa oloselu n fi agbada ro owo wo ile tiwon ni.
Opo won n ji owo, won n gba riba, ti won si n na owo ni inakunaa.
Awon onwoye so pe ni orile-ede yii kan naa ti N30,00 ko le te apo osise kan, a ri gomina to n gba owo to le ni ogorun milionu naira fun oun ti won pe ni owo aabo tiwon, iyen security vote, losu kan soso.
Ni ti awon amofin, nnkan ki si ese rago ni.
Opo omo Naijiria lo gba pe kokoro jowojowo ni won.
Bi a se n so yii, owo to n bo si apo enikan won losu, paapaa awon to wa ni Abuja, n le ni milionu merinla naira – losoosu! Eyi n waye ni ilu ti a ti n so pe a ko le san N30,o000 losu fun eni kan.
E je ki a wo iye ti N222,000 je ni owo dola ti awon oyinbo.
Die lo fi le ni aadorin dola – 70 dollars. Eyi buru jojo, ni ilu to je pe ile okeere ni opo oun ti a n lo ti wa, nibi ti lita epo betiro kan ti je N145.
Awon ibeere kan ti awon alase Naijiria tun ni lati bi ara won ni pe elo ni abo gaari ni 2010, elo si ni bayii? Elo ni epo betiro nigba naa, idameloo lo si ti fi po si bayii? Elo ni owo Milo, Bounvita tabi miliki nigba naa, elo wa ni bayii?
Elo ni owo ile iwe omo ni 10 bayii?
Ti a ba wo o daadaa, opo awon nnkan yii lo ti won ni ilopo meji ati ju bee lo.
Bi o ba ri bee, ko buru bi ijoba ba le gba ohun ti awon osise n fe lori sisan N30,000 fun osise to wa ni isale-sale ni ile ise kookan.
Awon gomina ti won n taku rangbondan sori N22, , nje won tile ronu jinle lati mo iye ti owo naa je lojumo?
Tipatipa lo fi ma ape N700. Bo ba je bee, e je ki awon gomina naa gbe gege le e, ki won so fun osise ti won ba n fun ni N22, 000 losu yoo se maa na a.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…