Home Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ Wahala APC ni Ogun: O seese ki Akinlade dije ninu egbe miiran
Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ - November 4, 2018

Wahala APC ni Ogun: O seese ki Akinlade dije ninu egbe miiran

Oludije gomina ninu egbe APC ni Ipinle Ogun, Alagba Adekunle Akinlade, ti so pe oun ati awon eniyan oun ko fara mo ipinnu Alaga Egbe naa lapapo, Comrade Adams Oshiomhole, lori bi o se fi oruko Alagba Dapo Abiodun ranse si ajo eleto idibo INEC, gege bii eni ti yoo soju egbe naa ni Ogun.
Ogbagbo pe oun ni oun bori ibo abele gomina naa, ati pe Oshiomhole fe fi owo ola gba oun loju ni.
Ninu atejade kan to gbe jade lojo Satide, o ni opo eniyan lo ti n bi oun pe kin ni oun maa se bayii.
Nipa bee, o ni oun si setan lati dije fun ipo gomina naa, to si je pe Ohiomhole ko le da oun duro.
Eyi jo pe Akinlade le lo si egbe miiran.
Eyi ko si ni ya awon eniyan lenu ju, tori awon omoleyin Gomina Ibikunle Amosun kan ti se bee leyin ti ija sele laarin oun ati awon alase egbe naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…