Home Orisirisi Amosun pa owe mo Tinubu lori oro Dapo Abiodun ati Akinlade
Orisirisi - October 23, 2018

Amosun pa owe mo Tinubu lori oro Dapo Abiodun ati Akinlade

Gomna Ibikunle Amosun ti ja Asiwaju Bola Tinubu ati Oloye Olusegun Osoba ni eekanna lori surutu to n lo lowo ni ipinle naa, latari bi oludije maji se n ja fun ibo gomina ni.
Egbe APC lapapo ko fowo si Adekunle Akinlade ti Amosun fowo si, ti won si ti kede Dapo Abiodun gege bi eni ti Abuja yan laayo.
Nigba ti Amosun n soro ni Abeokuta lojo Monday, o bu enu ate lu Tinubu ati Osoba.
O ni pelu bi won se dake ti won ko mi ringindin lori awuyewuye naa, o jo pe ejo lowo ninu.
Koda, o ni oun gbagbo pe ilu Eko ni won ti dogbon si oro Abiodun, tori Amosun ni won ko dibo rara.
O ni ibo kan pere ti won di ni Ipinle Ogun, Akinlade ni won di I fun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…