Home Orisirisi Oro Ambode ati Sanwo-Olu fe dija sile laarin Eko ati Abuja
Orisirisi - October 3, 2018

Oro Ambode ati Sanwo-Olu fe dija sile laarin Eko ati Abuja

Oro idibo abele APC laarin Gomina Ambode ati Jide Sanwo-Olu ti fe da rugudu sile laarin awon alase egbe naa ni Eko ati ti awon alase apapo ni Abuja, eyi to mu ki egbe PDP maa da ofun tolo.
Awon ajo ti egbe naa yan lati Abuja ko fara mo ibo ti won di ni Ojo Isegun, nigba ti awon ti Eko ni ibo ti pari, Sanwo-olu si ti wole.
Koda, Asiwaju Bola Tinubu ati Alaga egbe naa ni Eko, Alagba Tunde Balogun, ni Sanwo-olu ti wole.
Gege bi adari awon ajo ti Abuja yan lati seto idibo naa, Alagba Ebiri se so, awon ko tii fun eni kankan lase lati dibo tori awon n seto naa leseese ni.
Sugbon sa o, Tinubu ni ohun ti Ebiri so naa dabi pe ejo fe lowo ninu.
Nigba ti oro ti Alaga egbe naa lapapo, Adams Oshiomhole, ko tii ye eniyan to, Aare Muhammadu Buhari ko tii so nnkan kan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…