Home Orisirisi Ambode gba fun Olorun, o ki Sanwo-Olu ku oriire
Orisirisi - October 3, 2018

Ambode gba fun Olorun, o ki Sanwo-Olu ku oriire

Yoruba bo, won ni ija ibi (molebi) kii gbe ro, afi ki elenu so enu.
Ija ibi nikan ko, ija oselu naa wa nibe.
Bayii, Gomina Ipinle Eko, Ogbeni Akinwunmi Ambode, ti ki alatako re tele, Alagba Babajide Sanwoolu, ku oriire bi o se bori ninu idije ti won jo se fun eni ti yo soju APC ninu ibo gomina odun to n bo.
Ija naa le koko bi oju eja, debi pe o di ohun ti ara ile ati ara oko n so.
Koda, elomiran fee soro odi.
Titi di aaro yii, awutyewuye wa lati Eko lo si Abuja, tori awon to dari io naa ni ko tii si ibo rara.
Sugbon, leyin o reyin, won kede Sanwo-olu gege bii gomina.
Nigba ti opo eniyan si n jaya pe boya Ambode ko ni gba, o ti ba ona miran yo.
Ninu atejade kan ni irole oni, o ki Sanwo-Olu ku oriire. O ni nitori ife egbe APC, oun yoo se gbogbo ohun to ba ye lati se atileyin fun.
Koda, o kan saara si Asiwaju Bola Tinubu naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…