Home Orisirisi Kin lo de ti awon Ijesa fe gbe Aregbesola subu ninu ibo gomina Osun?
Orisirisi - September 23, 2018

Kin lo de ti awon Ijesa fe gbe Aregbesola subu ninu ibo gomina Osun?

Ohun iyalenu lo je fun opo eniyan bi egbe PDP se bori APC ni ile Ijesa, ninu ibo ti won di lanaa.
Omo Ijesa paraku ni Gomina Rauf Aregbesola, sugbon Ademola Adeleke gbo ewuro si asoju APC, Gboyega Oyetola, loju ninu ibo gomina naa, iyen ni opo agbegbe Ijesa.
INEC ti n kede abajade ibo naa, nibi ti Adeleke ti wa niwaju Oyetola.
Esi ibo Osogbo nikan lo ku, ti awon egbe oselu mejeeji si n wo fetofeto lori re.
NiIlesa West Local Government, Oyetola ni 7251 nigba ti Adeleke ni 8286. Adeleke tun gbeye lowo Oyetola ni Obokun LG to si je pe APC lo bori ni Atakumosa.
Esi ibo to ba jade lati Osogbo ni yoo toka si olubori lapapo, sugbon o ti wa ninu itan pea won Ijesa fi aye han Aregbesola nigba to nilo won ju.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…