Home Orisirisi Wasiu Ayinde n binu si Dele Momodu lori bi orin Bukola Saraki
Orisirisi - September 18, 2018

Wasiu Ayinde n binu si Dele Momodu lori bi orin Bukola Saraki

Oro erongba Dokita Bukola Saraki lati di Aare Naijiria ti fe di surutu laarin oga onifuji, Wasiu Ayinde K1 de Ultimate, ati oga oniroyin, Dele Momdu.
Wasiu Ayinde n tele Aare Muhammadu Buhari, nigba ti Dele Momodu n se ipolongo fun Saraki.
Orin kan ti Wasiu ko fun Saraki ni igba die seyin, nibi to ti so pe o ye ni eni to ye ko di Aare, lo fa awuyewuye naa.
Ko to di pe Saraki fe di Aare ni Wasiu ti ko o; to si tun je pe ko to di pe o darapo mo Buhari ni.
Orin naa ni Saraki ati Dele Momodu wa hu jade bayii, ti Momodu si ju u si ori afefe.
O wa dabi eni pe Wasiu sese ko orin naa fun Saraki ni, eyi to je ko dabi eni pe onifuji naa fe je nile Oro ati ile Eegun.
Eyi fa ki inu bi Wasiu, to si gbe atejade kan sita, nibi to ti bu enu ate lu ete naa.
Ninu atejade naa ti Akowe Iroyin re, Ogbeni Kunle Rasheed, gbe sita, o ni ko si aniani pe ti Buhari loun n se.
Bi o tile je pe Wasiu ti fi ehonu re han lati ojo Monday, Momodu sit un orin naa gbe sita lori Instagram lonii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara Orẹ Òtítọ́jù Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bí a ṣe ń pà…