Home iroyin MC Oluomo de fila Ambode
iroyin - September 10, 2018

MC Oluomo de fila Ambode

Yoruba bo, won ni Satide ti yoo dara, Jimoo ni a ti maa n mo o. Eyi lo d’Ifa fun oga agba awon egbe onimoto, Alhaji Musiliu Akinsanya, to wo fila ti won ko oruko Gomina IPinle Eko, Ogbeni Akinwunmi Ambode, si gbagadagbagada.
Ojo Sunday ni MC Oluomo gbe fila naa gun ori ero alatagba Instagram, nibi ti oun ati opo akegbe ati emewa re ti te fila naa yeye ye.
Pelu bi won se se naa, awon ti won ni oye oselu Eko ti gba pe Asiwaju Bola Tinubu ti silekun eleekeji fun Ambode ni, tori won mo pe Asiwaju ati Oluomo, padi ni won.
Ko wa yani lenu pe ojo keji ti won ge fila naa ni Ambode funra re lo ra foomu, to si kede pe oun fe dije leekan sii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…