Home LÁGBO ÀRÍYÁ Idaamu Yinka Ayefele ati bi awon osere Yoruba se la oniruuru ajalu koja
LÁGBO ÀRÍYÁ - August 29, 2018

Idaamu Yinka Ayefele ati bi awon osere Yoruba se la oniruuru ajalu koja

downloadyusuf-olatunji-b7189027-fc9a-411c-b7ce-61614a32a01-resize-750images
Bi o tile je pe kii se gbogbo won ni ijoba wo ile won, opo awon osere Yoruba naa lo ti la laasigbo nla koja. Se eni ti yoo ga, ese re yoo tin-in-rin.
Eni kan pataki to koko maa n wa si okan awon eniyan niru asiko yii ni Fela Anikulapo-Kuti. O je eni kan to maa n ba ijoba fa wahala. Laye ijoba Obasanjo akoko, nigba to je ologun, won da awon soja si Afrika Shrine Fela to wa ni Jibowu ni Eko.
O buru debi pe Fela ni won ju iya oun sile lati ori oofusia, ti won sin a awon eniyan ni anaki ki won tun to fi ina si ile naa.
A ko si gbodo gbagbe pe opo igba ni won ju Fela si ewon. Eyin aasigbo naa ni Fela gbe awo orin UNKNOWN SOLDIER jade.
Olorin miiran to tun se agbako ijoba ni Oloogbe Hubert Ogunde. Laye oselu Awolowo, o gbe ere ati awo orin YORUBA RONU jade. Awon Awon ijoba Oloogbe Ladoke Akintola gba pe awon lo n ba wi. Nipa bee, won fiya je e.
Oloogbe Yusuf Olatuni ko jiya lowo ijoba, sugbon oun naa ri ajalu ijamba moto nla kan. Wahala naa le debi pe awon kan ni won ti gee se re nigba to wa ni osibitu. Leyin eyi ni Yusuf Olatunji korin Yegede won ko ge e…
Oloye Ebenezer Obey naa foju wina ri. Ina kan seru ba a nigba to sese n dide gege bi akorin. Eyi lo bi orin ‘Lopelope oyinbo onilekeji/ To n kigbe/ Faa…/ Faa../ Faaya faya ki panapana to de.”
King Sunny Ade naa maa ri wi ti won ba ni ko ro ti enu re. Ni asiko kan, o jiya pupo labe asia ile ise orin Abioro. Ni pataki, aisan nla kan se e ni nnkan bii odun 1991 to si je pe Olorun lo yo o.
Meloo ni a fe kan, meloo ni a fe wi? Awon sorosoro bii Olanrewaju Adepoju, Gbena Adeboye ati beee bee lo foju wina gidi. Leyin pe ijoba Babangida ba Lanrewaju Adepoju fa surutu, bi a se n soro yii, oju n dun un, ti ko si le da lo si ibi kankan. Ki Oba Olojo Oni da oju akewi pataki naa pada.
A ko le gbagbe orisiirisii adanwo ti Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister la koja. Lasiko kan, obinrin kan tie jade to ni oun ni oun bi i, bee Barrister mo pe Odere Sifawu ni iya oun. Iru awon wahala ti aye gbe si Dr Fuji nigba lo mu u korin OKIKI: “Okiki ti mo ni yi ko to o, Edumare/ Ba mi wa mii si o, Edumare…’
Leyin pe awon alaheso kede iku Kollington Ayinla bii eemeji, ina nla kan jo ile re ni Alagbado. Asiko naa ni iyawo re kekere kan to loyun ku, pelu iroyin pe won so pe ki o seyun ni. Alhaja Salawa Abeni ni won toka si. Ibinu eyi ni oun ati Kebe n Kwara fi ko ara won sile titi di oni olonii.to je ni o korin ‘Won so pe mo ku, ariwo gbale,/ Okiki kan ja gbogbo Naijiria….’
Dauda Akanmu Epo Akara naa kare lona orun. A ko le gbagbe bi moto oun ati awon elegbe re re se se konge ijamba moto ni eti Alapako lona Ibadan. Won n ti Eko ti won ti lo sere bo lojo naa ni. Eniyan mejeeji otooto – Omoboade ati Dauda – ni won je Olorun nipe nigba naa. Asiko yii ni Epo Akara korin ‘Ni o f’abo f’Olorun lorun/ Ni o f’abo f’Olorun lorun/ Asiko tonikaluku ba yan/ Asiko tonikaluku ba yan/ Ni o f’abo f’Olorun lorun…”
Bakan naa, a ko gbodo gbagbe pe Oloogbe Orlando Owoh lo si ewon lori esun igbo, to fi wa korn E GET AS E BE nigba to jade. E get as e be…, o nib o se je.
Ayinla Omowura ti ko wo ewon, gbogbo bo se lagbara to, won gun nigo pa ni. Eyi tumo sip e, loooto, ko si eni to koja adanwo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…