Home Orisirisi Oro gbeyin yo, Ajimobi se ipade pelu Yinka Ayefele
Orisirisi - August 24, 2018

Oro gbeyin yo, Ajimobi se ipade pelu Yinka Ayefele

Oro awon oloselu, nnkan nla ni. Eyi lo d’Ifa fun Gomina Ipinle Oyo, Senito Abiola Ajimobi, to ti ba gbajugbaja akorin, Yinka Ayefele, se ipade po lanaa, ni ile ijoba to wa ni Ibadan.
Gomina ti wa so pe won maa da ajo komiti kan sile lati wo igbese ti won ni lati gbe lori isele ara ile Ayefele ti won wo ni Orita Challenge, Ibadan.
Opo eniyan lo bu enu ate lu gomina lori igbese ile wiwo naa, sugbon oun naa ni ika to ba se ni oba a ge ni oun se e.
Sugbon lasiko ipade naa, Ajimobi ni eniyan daadaa ni Ayefele, sugbon ko si anfaani ninu ki a maa se si ofin ile kiko.
Ayefele naa ni gbogbo ohun ti ijoba ni ki oun se ni oun se, sugbon awon ojise gomina ni ko fun oun laye lati ri i lasiko.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…