Home Orisirisi Idi ti Awujale fi fe gbe awon eniyan kan sepe ni Ojude Oba
Orisirisi - August 24, 2018

Idi ti Awujale fi fe gbe awon eniyan kan sepe ni Ojude Oba

downloadOju-e1473921199419
Ohun kan ti ko sele ri lasiko ajodun nla ti Ojude Oba sele ni ojo Alaisi, nigba ti Awujale ti ile Ijebu, Oba Sikiru Adetona, leri lati gbe awon eniyan kan sepe.
Ajodun Ojude Oba naa dun, o rinle, tie se ko si gbero ni Ijebu Ode nigba ti o n waye.
Awon Regberegbe dan mwaa wo ninu awon aso oniruuru, ti won n jo, ti won si n yo.
Bi onijo se n jo ni awon Elesin n gun esin iyen idile awon Balogun.
Leyin pea won alaguda je ki kinni naa o larinrin, Musiliu Haruna Ishola wa nikale, to n fi orin apala da won lara ya.
Sugbon nigba tie to naa fee de opin, awon omoleyin awon oloselu kan wo inu gbagede ajodun lo. Won mu igbale awon APC lowo, ti won sib ere sii korin oselu.
Eyi waye lati fi ilodi si won han lori bi wiwa ti Aaare Ile Igbimo Asofin Agba, Dokita Bukola Saraki, se wa nibi odun naa.
Nigba ti won bere sii se bee, Awujale ranse si won pe ki won dake, o ni eto asa ati ise ni Ojude Oba, kii se ti oselu.
Sugbon nigba ti won ko dake, Kabiyesi ni ise ni won fe f’ori ko resua, tori oun setan lati s’epe fun awon to bat un n na igbale soke, ti wn si n korin oselu.
Awon eniyan naa dake lasiko yii, sugbon nigba ti Saraki bere sii soro, won tun bere sii ju igbale soke laa, ti won si n korin lati di I lowo.
Ohun ti a ko wa mo ni bi Awujale se bi o se wi fun won, tabi Kabiyesi je Ebure – Ebure awo olugbebe.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…