Home Orisirisi Lojo Ileya, awon omo Naijiria kan Saraki l’abuku
Orisirisi - August 21, 2018

Lojo Ileya, awon omo Naijiria kan Saraki l’abuku

Aare Ile Igbimo Asofin Agba, Dokita Bukola Saraki, kan abuku olorombo ni owuro yii, nigba ti awon omo Naijiria kan hanyin mo o lori oro iwuri to so lati se ayajo odun Ileya.
Jeje Saraki lo sori ero alatagba Instagram, to si so pe ki gbogbo omo Naijiria lo anfaani odun Ileya ati bi opo Musulumi se n goke Arafa lati ro ero, ati hu iwa ti yoo gbe Naijiria de ebute ogo.
Oro yi gba odi lo lokan opo eniyan, ti won si bere sii so oro buruku si Saraki.
Won ni Saraki ati awon oloselu Naijiria yoku naa ni eku to da eyi sile to n je eda.
Won ni awon naa ni ajegirun ti ko je ki igi Naijiria so eso rere.
Awon kan tile so pe bi Saraki ba lero pe oun le fi juju esin boa won loju, iro funfun balau lo pa.
Sugbon sa o, awon eniyan kan naa si kan saara si i, ti won si ni ko maa ba faaji bo.
Lara awon to soko oro lu Saraki lori Instagram ni Abdufatai Oludare, EmiraltyAfrica ati Domcalluci.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara Orẹ Òtítọ́jù Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bí a ṣe ń pà…