Home Orisirisi Paga! Ijoba Ajimobi wo ile Yinka Ayefele
Orisirisi - August 19, 2018

Paga! Ijoba Ajimobi wo ile Yinka Ayefele

yinka Ayefele music houseAyefele-and-Gov.-Abiola-Ajimobi
Ajalu nla wole ba akorin Tungba, Yinka Ayefele, ni idaji oni.
Ijoba Ipinle Oyo ti wo ile ise re to wa ni Orita Challenge ni Ibadan.
Eyi waye leyin ti Ijoba Ajimobi ati Ayefele ti leri sira won fun igba die, debi pe Ayefele gbe ijoba naa lo sile ejo.
Bi o tile je pe ijoba naa ko tii so oro kankan, awon enyan to wo lo si ibe, ti won ri bi katapila bulldozer se fa ile naa ya yannayanna mo ibi ti ina ti dahun.
Esun ti ijoba fi kan Ayefele nip e ile naa, nibi ti ile ise re, Fresh FM wa, duro si ibi ti ona ye ko balo.
Bakan naa, a gbo pe won ni ko tele oun to so fun ijoba pe oun fe fi ile naa se, iyen ofiifi (office complex).
Bayii, Ayefele ti so pe iro ni gbogbo esun ti ijoba ka si oun lese.
O ni gbogbo iwe to ye ki oun gba lowo ijoba ni oun gba.
Bakan naa, akowe iroyin re, David Ajiboye, ti so pe bi ijoba se wo ile naa ko da okan awon laamu ju.
O ni won le wo ile ni, won ko le mu ki opin de ba Fresh FM.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara Orẹ Òtítọ́jù Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bí a ṣe ń pà…