Home ỌRỌ̀-AJÉ Mo lowo ju Dangote lo – Oluwo
ỌRỌ̀-AJÉ - August 4, 2018

Mo lowo ju Dangote lo – Oluwo

Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdurasheed Akanbi, ti so pe oun lowo ju gbajugbaja bilionia, Alhaji Aliko Dangote, lo.
Dangote, eni to je onise okowo nla, to je Aare Dangote Group of Companies, lo lowo julo ni gbogbo Aafirika.
Koda owo naa po de gongo, to si je pe yoo tun bureke laipe yii, nigba ti ile ise fopofopo re – refinery – ba bere sii sise.
Bawo wa ni Oluwo se lowo ju okunrin naa lo?
Sugbon sa o, Kabiyesi fi oro naa se akawe ni. Nigba ti o n ki awon eniyan ilu, o se adura nla pe ki Olorun je ki won lola, ki won lokiki ju awon oba alaye lo.
O ni eyi ni adura ti baba gbodo maa gba fun omo, tori omo ni gbogbo eniyan je fun oba, kiba je olowo, kibaa je talika.
Oluwo ni gege bi oba abe asia un ni gbogbo olowo wa, tori oba lo ba lori ohun gbogbo.
O ni idi niyii ti oun fi lowo ju Dangote lo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…