Home Orisirisi Lai Mohammed gbona eburu yo si Saraki ni Kwara
Orisirisi - July 29, 2018

Lai Mohammed gbona eburu yo si Saraki ni Kwara


Minisita fun Oro Iroyin ati Asa, Alhaji Lai Mohammed, dan mewaa wo ni ilu Oro, ni Ipinle Kwara lonii, nigba to lo se ipade nla pataki kan lori ati je ki egbe APC tubo fidi mule sii ni Kwara.
Opolopo omo egbe lo suuru bo o, ti oun naa si n mu u da won loju pe APC Ilorin wa fun Aare Muhammadu Buhari ti Buhari naa si wa fun won.
Ipade to ba awon leekan-leekan egbe se mu ipinnu pataki bii marun-un wa.
Lona kinni, won ni niwon igba ti awon asofin kan ti fi egbe APC sile, awon alakoso egbe ti Balogun Fulani je olori won gbodo kowe fi ipo won sile, ki awon eniyan ti o nifee egbe denu sib o sipo.
Lona keji, won ni gbogbo awon ti won lo asia egbe lati gba ipo ninu ijoba gbodo kowe fi ipo naa sile.
Lona keta, won ni lilo awon asofin kan ti foju awon to feran egbe denu han, ti APC si ni omo asofin to po ju ti PDP.
Won tun so pe ko si ani-ani pe ti Aare Buhari ni awon eniyan Ipinle Kwara n se.
Ni ipari, ipade ro awon omo egbe ki won ni suuru, ki won ma ja, tori ago Buhari lo maa de adie ni 2019.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…