Home Orisirisi Akin Ogunbiyi: Ohun ti e ko mo nipa eni to n ba Ademola Adeleke du ipo oludije gomina ni PDP
Orisirisi - July 23, 2018

Akin Ogunbiyi: Ohun ti e ko mo nipa eni to n ba Ademola Adeleke du ipo oludije gomina ni PDP

Opo lo ti n so pe anfaani nla ni bi Senito Ademola Adeleke se wa ni idile olowo je fun un lori idibo gomina to n bo ni Osun, ati lori bi o se bori gege bii oludije fun PDP.
Sugbon ohun ti won ko mo ni pe eni to ba a du ipo naa, ti o je pe ibo bii merin pere lo fig be e, iyen Dokita Akin Ogunbiyi, naa kii se otosi.
Dipo bee, olowo tabua ni oun naa.
Gege bi egbon Senito Ademola Adeleke se ibu owo, nipa ise okowo, ni Ogunbiyi naa je.
Bi apeere, Ogunbiyi ni oludasile ile ise adojutofo nla kan ti a mo si Mutual Benefit Assurance. Eyi nikan ko; won tun ni o ni agbami epo robi ti won n pe ni oil bloc.
Eyi tumo sip e ninu ifigbagbaga awon mejeeji, eegun kan eegun ni, to si e pe irin kan irin.
Ni bayii, Ogunniyi ti fi ehonu han fun awon olori egbe PDP lori abajade ibo ebele Satide. O ni mogomogo wa nibe, ati pe o ye ki oun ni ibo ju Adeleke lo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…