Home LÁGBO ÀRÍYÁ Charly Boy gba kamu lori omobinrin re to fi omobinrin miiran se iyawo
LÁGBO ÀRÍYÁ - July 22, 2018

Charly Boy gba kamu lori omobinrin re to fi omobinrin miiran se iyawo


Kogberegbe akorin ti a mo si Charly Boy ti gba kamu lori omobinrin re kan ti o ti fi omobinrin miiran se iyawo bayii.
Bi omobinrin naa ti oruko re n je Dewy se lewa to, dipo ki o fi okunrin se ololufe, obinrin miiran lo yan laayo, eyi ti awon oloyinbo n pe ni lesbianism.
Nigba ti Charly Boy n soro lori isele naa, o ni awon omo oun yoku ti n di loko-laya ni liana okunrin elu obinrin, sugbon lesbianism naa ni Dewy yan laayo.
O ni niwon igba to je pe idunnu omo oun lo je oun logun, ko si ohun ti oun fe se ju pe ki oun ko le ko o lomo.
Charly Boy ni oun ko beru rara lori pe boya ijoba le fe fiya je omo naa nitori ofin to de ki okunrin fe ara won ati ki obinrin fe ara won.
O ni laarin awon asofin gan-an ti won se ofin naa, ati laarin awon alase ijoba ti won fe ki ofin di amuse, opo won lo je pe okunrin-fe-okunrin ati obinrin-fe-obinrin ni won.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…