Home Orisirisi Ta ni yoo soju APC ninu ibo gomina Osun?
Orisirisi - July 20, 2018

Ta ni yoo soju APC ninu ibo gomina Osun?

Bi awuyewuye ibo gomina Ekiti se n lo sile yii, okan awon amoye tun ti n lo si Ipinle Osun o.
Laipe yii ni ibo gomina Osun naa yoo waye, nigba ti Gomina Rauf Aregbesola yoo ti pari odun mejo re.
Oni gan-an ni APC fe dibo yan eni ti yoo soju won, tori enu won ko ko lori eyi tele.
Bi ibo naa se n waye, eni kan ti oju wa lara re ju ni Alagba Gboyega Oyetola, eni to se Alakose awon osise oba (Chief of Staff) fun Aregbesola.
Igagbo awon eniyan ni pe Oyetola ni Aregbe foju si lara, ti awon kan si so pe ibatan Asiwaju Bola Tinubu ni.
Lara awon ti won n kopa ninu idibo oni ni Onarebu Lasun Yusuff; Dokita Najeem Salam; Senito Babajide Omoworare Alhaji Moshood Adeoti, Oloye Ezekiel Oyemom, Alagba Saka Layonu , Abdulgafar Amere atid Kunle Adegoke.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…