Home Orisirisi Ija to wa laarin Liz Anjorin tun hu jade lagbo Pasuma
Orisirisi - July 17, 2018

Ija to wa laarin Liz Anjorin tun hu jade lagbo Pasuma

Yoruba bo won ni egbinrin ote, bi a ti n pana okan ni okan tun n ru.
Eyi lo difa fun ija to wa laarin osere Yoruba meji kan, iyen Ronke Osodi Oke ati Liz Anjorin.
Ni nnkan bii osu kan seyin ni awon mejeeji bu ara won bi eni maa ku, latari bi Ronke Osodi Oke se soro si awon gbajumo kan to ni won n se sekarimi.
Nigba ti awon mejeeji tun pade lagbo Wasiu Alabi Pasuma, ni ilu Eko ni kopokope yii, oro naa ma tun hu jade.
Nigba ti Ronke n soro nibe, o tun menu baa oro awon omo oninakunaa nibe. Bee, Liz Anjorin fi owo mo Pasuma lori.
Eyi bi Liz Anjorin ninu gidi, to si ti ko o jade lori ero alatagba pe lojo ti Ronke ba tun ba oun da a lasa wo loju agba, gbadogbado yoo gba owo agbado lowo re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…