Orisirisi - July 15, 2018

Ori tako Croatia, France lo gbe World Cup lo

Orisa boolu rerin-in si orile-ede France ni ojo Sunday, nigba ti won gba ife eye agbaye ti World Cup.

France na Croatia pelu ami ayo merin si meji.

Bi o tile je pe Croatia gba boolu daadaa, ori won tako won die. Idi ni pe funra won ni won gba ami ayo akoko wole ara won, eyi ti awon oloyinbo n pe ni own goal.

Goolu eleekeji to wo ile won naa, penariti ni, nigba ti okan lara won fi warawara fi owo gbe boolu.

Omo to gba boolu bi elewele, Mbappe, ati Pogba naa ri goolu kookan.

Pelu bi France ti gba ife eye naa, o tumo si pe ife eye ti won gba keyin ni 1998 ni won tun gba yii.

Won fakoyo nibi ti awon orile-ede to le gba boolu, ti won si wa ni World Cup, ti won ko si le debi giga ninu idije naa.

Awon naa ni Argentina, Germany, France ati Brazil.

Ohun to pani lerin-in die nibi idije naa nip e, leyin ti ayo naa pari, bi awon to padanu koobu naa se n sunkun, ni awon ti won gba ife eye naa n sunkun. Ekun iyanu, ekun idunnu, ekun ayo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…