Home ERÉ ÌDÁRAYÁ RUSSIA 2018: FRANCE ATI CROATIA NINU ITAN
ERÉ ÌDÁRAYÁ - July 14, 2018

RUSSIA 2018: FRANCE ATI CROATIA NINU ITAN

RUSSIA 2018: FRANCE ATI CROATIA NINU ITAN
– Lati owo Akinwale Taophic.
“A o pagbo, a o pagbo, nigbeyin gbeyin, obe tan ni yoo gbeyin odidi maluu”. Idije ife eye agbaye ti odun 2018 ti wa si opin bayii, ninu eyi ti orisirisi itan ti tun ara won ko, ti awon itan tuntun miran si je jade.
Itan tuntun ni pipade ti orileede France ati Croatia pade ni asekagba je, nitori wi pe orileede mejeeji ti pade ni igba marun-un otooto ri, eyi ti ko si asekagba idije ife eye agbaye nibe rara ayafi igba ti won pade ni ipele ti o kangun si asekagba (semi final) ni odun 1998 ninu eyi ti orileede France ti bori Croatia pelu ami ayo meji si eyo kan (2-1). Orileede France ni o gba alejo ife eye agbaye ni odun naa ninu eyi ti won ti bori orileede Brazil ni asekagba.
Gege bi itan ti o wa ni akosile, France ati Croatia ti gbena wo oju ara won ninu ifigagbaga boolu alafesegba ni igba marun-un, orileede France bori ni igba meta, ni igba ti won gba ayo omi ni inu ifigagbaga meji ti o ku.
Awon ifigagbaga naa ni wonyi:
France 2 – 1 Croatia. July 8, 1998
France 3 – 1 Croatia. Nov 13, 1999
France 2 – 0 Croatia. May 28, 2000
France 2 – 2 Croatia. June 17, 2004
France 0 – 0 Croatia March 29, 2011

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…