Home ERÉ ÌDÁRAYÁ Suegbe na pako: England gbe ounje ale re fun olongbo Croatia je
ERÉ ÌDÁRAYÁ - July 11, 2018

Suegbe na pako: England gbe ounje ale re fun olongbo Croatia je

Egbe agbaboolu England fi ainikan-anse ko ba ara won ni ale oni, nigba ti won koju Croatia ninu idije World Cup to n lo lowo.
Nipa bee, Croatia ti le won lugbe pelu ami ayo meji si okan.
England lo koko ri goolu, sugbon won ko fara sise daadaa mo lati igba naa.
Kerekere ni Croatia ri goolu akoko, to si ri eekeji lasiko afikun extra time.
Omo England to maa n gba boolu wole daadaa ko tie rowo mu rara, o kan n fo lente lente kaakiri ori papa ni bi opolo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…