Home Orisirisi Nitori Fayemi, Aregbe, Akeredolu jo ijo LEGBEGBE. Wasiu Ayinde ati Tinubu se collabo
Orisirisi - July 10, 2018

Nitori Fayemi, Aregbe, Akeredolu jo ijo LEGBEGBE. Wasiu Ayinde ati Tinubu se collabo

Mewaa sele ni Ado Ekiti lonii nigba ti egbe APC se ipolongo ibo fun aoju won ninu ibo Satide to n bo, Dokita Kayode Fayemi.
Opolopo olori egbe, to fi mo Aare Muhammadu Buhari ati Asiwaju Bola Tinubu, lo pe sibe.
Ninu awon ohun to pa awon oludibo lerin-in nibe ni bi awon oloye egbe naa ti fi ijo da awon oludibo lara ya.
Bi apeere, Wasiu Ayinde K1 de Ultimate lo n ju orin si eto ipolongo naa lore koore.
Kinni naa le koko debi pe Minisita fun Oro Awon Osise, Dokita Chris Ngige, eni to je omo Igbo, ati Alaga Egbe APC, Alagba Adams Oshiomhole, to je omo Edo, naa jo ijo fuji Wasiu.
Asiko ti Tinubu n soro gan-an ni o da bi eni pe oun ati Wasiu ti jo se se apero tele lori bi won yoo se se kolabo nibi ipolongo ibo naa. Bi Wasiu se n ju u ni Tinubu n han-an, ti opo eniyan si n patewo.
Ko wa tan sibe o, Gomina Ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola, ati Gomina ti Ipinle Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, naa fihan pea won mo ohun to n lo nigba ti won ki ijo omokunrin oni hip hop ti a mo si Mr Real mole, ninu orin re LEGBEGBE.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…