Home Orisirisi Iku Khadijat: Igbakeji gomina ni won fomo oun soogun owo ni
Orisirisi - July 10, 2018

Iku Khadijat: Igbakeji gomina ni won fomo oun soogun owo ni


Imole die ti tan si iku to pa arabinrin Khadijat Oluboyo, eni ti won ba oku re ni abe beedi arakunrin kan ni ilu Akure.
Baba omo naa, to je Igbakeji Gomina Ipinle Ondo lasiko Mimiko, Alhaji Lasisi Oluboyo, so ni ana pe awon onise ibi lo fi omo se oogun, leyii to le je oogun owo tabi nnkan miiran, eyi ti awon oloyinbo n pe ni rirual killing,
Alhaji Oluboyo so pe ara bere sii fu idile oun nigba ti oun fi owo ranse si oma naa, ni ifafiti Adekunle Ajasin to wa, sugbon ti oun ko gbo kop e oun lati dupe nigba ti o ri alaati – gege bi o ti maa n se tele.
O ni lati igba naa, awon ko gboun omo naa, titi di igba ti won ba oku re ni abe beedi okunrin kan ti won pe oruko re ni Adeyemi Alao.
Sugbon sa o, Alagba Lasisi Oluboyo ni oun ko ni gbe oro naa lo sile ejo, o ni oun fa awon to wa nidii laabi naa si kootu Olorun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Mi ò gba owó oṣù fún ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ọ̀sun

Mi ò gba owó oṣù fún ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ọ̀sun Ọrẹ Òtítọ́jù Minisita ọrọ abẹle…