Home Orisirisi Oluwo fun Ooni ni oruko miiran
Orisirisi - July 9, 2018

Oluwo fun Ooni ni oruko miiran

Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdurasheed Akanbi, feran ki o maa so ara re ni oruko nla nla. Lara awon apeje ti Kabiyesi ti so ara re ni Telu of Africa ati Emperor, to tumo si alagbara nla.
Nigba miiran, oruko to ba nawo mu maa n da awuyewuye sile. Peere eyi ni igba ti Kabiyesi ni oun ko je Oba mo, to ni Emir ni oun, nitori o gba pea won oba Hausa/Fulani kii maa n je ara won lese bii ti Yoruba.
Oruko miiran to tun wu Oluwo ni Alase-lori-orisa. O mu oruko yii lati fi ye awon eniyan pe oun kii se egbe awon orisa, debi pe won yoo ma ape oun ni Alase-ekeji-orisa ti won n pe oba Yoruba miiran.
Ni bayii, Oluwo ti fun Ooni ti Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, ni oruko naa.
O se eyi nigba to se atejade foto kan ti won jo ya laipe yii, nibi to ti se apejuwe Oba Ogunwusi bii, ‘Arole Eledumare, Alase Lori OrisaKabiyesi Oonirisa Ojaja 2’.
Ohun ti a ko tii mo ni boya Ooni nifee si oruko ‘Alase Lori Orisa’ naa, tabi ‘Alase Ekeji Orisa’ ni won fe maa je.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…