Home iroyin Akowe ACOMRON lu olokada pa pelu oruka aluwo
iroyin - July 6, 2018

Akowe ACOMRON lu olokada pa pelu oruka aluwo

Wahala nla be sile ni ilu Abeokuta nigba ti okan lara awon oloye egbe olokada ti a mo si ACOMRON ju ese lu okunrin kan to n gun okada, ti onitohun subu lule, to si gba ibe lo si orun alakeji.
A gbo pe oruko eni to gba eniyan ni ese ni Saheed, nigba ti eni to pa n je Ibrahim Raji.
Iroyin ni Saheed beere owo tikeeti to je N150, sugbon Raji ko fun un.
Raji ni oun kii se olokada to n gbero, ati pe birikila ni oun.
Sibesibe, Saheed ko gba, to si gba Ibrahim ni ese.
Ibe lo subu si kota si, ti o si ku ki won to gbe e lo si osibitu.
A gbo pe oruka buruku kan to wa lowo Saheed lo da wahala sile.
Abenugan awon olopaa ni Ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi, so pe ooto ni isele naa sele, to si je pe Saheed si wa ni odo awon.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…