Home iroyin Fayọse fẹ̀sùn òjóró kan INEC
iroyin - July 4, 2018

Fayọse fẹ̀sùn òjóró kan INEC

Gomina ipinle Ekiti, oloye Ayodele Fayose lo ti fi esun ojoro sise lati segbe leyin egbe oselu APC kan ajo INEC to n dari eto idibo ile wa. O ni ogbon jibiti kan ti wa ninu apoti eto idibo ti won ti lo dogbon si.
Komisona eto idibo ni ipinle naa, abileko Aminat Zakari ni ki Oloye Foyose mu eri to daju wa, nitori pe gbogbo ohun ti o n daruko pe o ni ojoro ni ko see dogbon si rara, arabinrin naa ni ko tile le gba ibo kankan ti ko ba di ojo idibo ti awon se gbogbo eto imo ero komputa sii lati le je ki o se lo.
Komisona eto idibo yii ni ko dara bi Gomina Fayose se n gbe iro kiri nitori pe eyi le ba awon ara ilu lokan je ki won si fe da ilu ru lori iro lasan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…