Home Orisirisi Ajalu ina tanka: Ara Eko si n beru boya oosa mujemuje kan wa lori biriiji Otedola
Orisirisi - July 3, 2018

Ajalu ina tanka: Ara Eko si n beru boya oosa mujemuje kan wa lori biriiji Otedola

O ti di eniyan mejila to ku ninu ina naa
Aajo omo lo pa okunrin kan, obinrin kan si n wa ibeji re
Ainiye owo, laptop, foonu ati dukia miiran jona guagua
Ambode fi ofin de awon ajagbe ejo

Ijamba moto buruku kan to tun sele lojo Alamisi to lo ti da ibanuje ati ifoya miiran sile laarin opolopo awon eniyan Eko ati awon miiran to n gba biriiji Otedola – iyen Otedola Bridge – koja.
Ojo ibi at’akoko to je manigbagbe loj’Obo, Thursday,ojo kejidinlogun osu kefa odun yii je fun opolopo idile nipinle Eko pelu bi oko ajagbe agb’epo kan to n gba agbegbe Berger koja lojo naa se padanu ijanu re to si tipase bee kolu opolopo oko to to lowoowo leba opopona naa leyi to fa ina airotele nibi t’eeyan mesan-an otooto ti jona koja aala t’awon oko ti ko din ni merinlelaadota si jona patapata.
Ajagbe Ejo kan lo da wo lule, to si gbina to sit a ina ajooku si opolopo oto lara, tori pe o gbe epo betiroolu.
Eniyan mesan lo jona guagua sinu moto won, nigba ti opo eniyan fara pa. A tile gbo pea won meta miiran tun ti ku.
Moto bii merinlelaadota lo jona, eyi to tumo sip e opo dukia lo jona, tori a ko tie mo iye owo ati ohun meremere miiran to jona monu awn moto naa.
A gbo pe Olorun lo yo awn omo ile iwe aladani kan to wa ni adugbo Ikosi. Bi ina se se bula, ni awon omo naa sare be jade.
Ninu moto ayokele kan, bi ina se bere sii jo, okunrin to ni moto naa sare be jade. Sugbon awon omo re meta to wa ninu moto naa ko mo eyi ti won yoo se. Eyi lo fa a ti baba naa se sare pada sibe, pe ki oun tile sare fa won no sita. Sugbon sa o, ibe ni gbogbo won jade si.
Bi onikaluku se n ja poro yii, ohun ti eni kan ko tun le so ni ti dukia to jo ninu awon moto naa. Lara won ni owo naira ati ti ile okeere, komputa, paapaa laptops t orisiirisii akosile wa ninu won, opolopo foonu ati bee bee lo.
Nitori pe afara naa lo ja si agbegbe Berger ti awon to n lo si Ibadan ati opo ilu miiran n gba, ainiye moto ko le koja.
Won wa ni oju kan, ti won si se sun keere, gba keere fun opolopo wakati.
Ki a ma fa oro gun, ojo keji ni apa awon agbofinro to le ka laasigbo naa.
Gomina Ipinle Eko, Ogbeni Akinwunmi Ambode, naa sare lo sibi ajalu naa, ti Aare Muhammadu Buhari ati opo eniyan ti ara n ta naa si ba awon ti ajalu ba kedun.
Titi di a ti n soro yii, awon to ni eniyan ni adugbo naa, tabi to mo pe molebi ati ore won n rin inrin ajo, si n pe won lori foonu ni o.
Won fe mo daju pe Olorun ko je ki won wa ninu ewu naa.
Bi eyi se wa n lo ni awon kan n ko ominu lori ohun to saaba maa n fa ijamba lori afara Otedola naa.
Won so biriiji naa ni Otedola Bridge tori o wa niwaju adugbo awon ile akogbe ti a mo si Otedola Estate.
Ijoba Eko lo so ibe ni oruko yii, lati bu ola kun Gomina Eko nigba kan, Alagba … Otedola.
Awon to n ro bayii n so pe boya emi buruku kan wa lori tabi labe afara naa to maa n mu eje nigba to be wu u.
Latari eyi, won ni ki awon to n gba ona yii kun fun adura pupo, nigba ti awon kan ni boya ipese tabi ebo kan ni emikemii naa fe gba.
Ohun to tun da kun wahala naa ni pe ni ojo keji ti tanka jona, asidenti miiran tun sele, nigba ti moto faragon kan fori gbari pelu boosi miiran.
Sugbon sa o, awon ti won ko gbagbo ninu iru ero bayii ti so pe ijoba ati awn eniyan ni ko se ohun to ye ki won o se.
Won ni arun oju ni ijamba to n sele lori Otedola Bridge.
Lona kinni, won ni ori awon onimo-ero – engineer – to se afara naa kop e rara. Won nib o se dorikodo n fa wahala fun awon awako, paapaa awon onitirela.
Bakan naa ni odo wa ni abe re, ti ko si si irin gidi kan to wa ni apa otun ati osi ona naa.
Won wa ro ijoba Ipinle Eko ati ijoba apapo ki won ww woroko fi sadaa.
Won tun bu enu ate lu awon direba moto nla nla naa ti kii ni ifura to, ti won si n sare asapajude lori re.
Nigba ti awon eniyan kan ran ijoba leti pe ofin kan wa to so pe oru ni ki awon ajagbe ejo maa rin, won kan tun ni awon direba moto keekeeke bii danfo ati faragon naa ni lowo, won tun di siese.
Won ni awon gan-an naa n fa opo ijamba. Bi apeere, awon kan ti isele Otedola Bridge soju re ni onimoto faragon kan lo da laabi naa sile, nigba to ko si moto elepo naa lenu.
Afi ki Olorun ba ni mu wahala ori Otedola Bridge duro, ki Edumare sit e awon to ti ku si afefe rere.
Lara awon iroyin to tun ti n jade lori isele naa ni pe awon ebi kan si n wa eniyan won.
Lara won ni omodekunrin kan, Eyitayo Famojuro, ti awon obi re n wa.
Ibeji ni omo odun meta naa. Oun ati iya re, pelu ekeji re, Eyotoke, ni won jo wa ninu moto nigba ti ijamba naa sele.
Won wa ke gbajare pe eni to ba ba won ri omo naa ko ta won lolobo.
Bakan naa, a gbo pe oorun awon to jona ti gbale ni adugbo naa.
Sugbon sa o, okan lara awon ti isele naa soju re bu enu ate lu awon alase Otedola Estate. Won ni won ko gba awon eniyan laaye lati sa wo ibe nigba ti oju ogun le.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…