Home iroyin Pastor Tunde Bakare soro lori iku iya re
iroyin - July 1, 2018

Pastor Tunde Bakare soro lori iku iya re

Oro iya le pupo lara omo. Idi niyi to fi je pe ko si bi omo se dagba to, ko si si bi iya eni se darugbo to ko to ku, ojo to ba lo si alukiamo, o si maa n dun eniyan wonu egungun ni.
Eyi lo n sele lowolowo bayii ninu aye oludasile soosi Latter Rain Assembly, Pastor Tunde Bakare.
Pastor naa sese sin oku iya re, Mama Abigail Eebudola Bakare, ni, ni ilu won ni Abeokuta.
Opo eniyan nla nla lo lo ba Bakre se isinku naa, titi to fi dori Igbakeji Aare, Ojogbon Yemi Osinbajo, Asiwaju Bola Tinubu ati Gomina Ibikunle Amosu.
Nigba ti Pastor Bakare n soro nibi isinku naa, o ni iku iya naa ka oun lara.
O ni o da bi igba ti apa kan ninu ara oun sonu ni, tori iya naa je iya daadaa to sise fun ilosiwaju oun.
Koda, Bakare naa se bi omode, o ni iya oun mo obe se daadaa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Nàìjíríà sì nílò Ọbásanjọ́ fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí- Buhari

Nàìjíríà sì nílò Ọbásanjọ́ fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí- Buhari Fẹ́…