Home Orisirisi Idi ti mo fi se igbeyawo eleekeji – Ibrahim Chatta
Orisirisi - July 1, 2018

Idi ti mo fi se igbeyawo eleekeji – Ibrahim Chatta

Ojulowo osere Yoruba kan, to je pe ko si ipa ti kii ko daadaa, Ibrahim Chatta, ti se alaye bi igbeyawo re akoko se fori sanpon, ti o si se igbeyawo miiran.
O so ninu iforowanilenuwo kan pe ina ife (love) to ku laarin oun ati iyawo oun akoko naa, ti oruko re n je Salamotu, lo fa ituka.
O so pe bi o tile je pea won mejeeji nifee ara won tele, awon ri i pe ko si ife mo nigba to ya.
Ibrahim Chatta so pe obinrin naa tie so fun ohun pe latigba ti awon ti se Nikai tan ni ife oun ti kuro lokan re.
O ni oun bi o tile je pe oun naa ko nife Salamotu mo, oun gbiyanju titi ki igbeyawo naa ma daru, ki awon si pada si aaye ti awon wa tele.
Ibrahim wa so pe sugbon ko si bi a se se ebolo ti ko ni run ti ayan naa ni oro naa ja si.
O ni iro funfun balau ni awon kan to so pe oun maa n na obinrin pa mo oun.
O ni iyawo oun akoko naa, omo Senito ni. Osere naa wa beere pe se o seese ki eni kan maa lu omo Senito bi eni lu baara.
Ibrahim Chatta fi kun un pe oun ti bimo kan tele ki oun to fe Salamotu, sugbon oun ko se igbeyawo pelu iya omo naa.
Sugbon bayii o, o ti fe obinrin miiran, to si je pe idile alayo ni idile re.
Ibrahim seranti bi o se sa ni ile iwe lati se ise tiata, sugbon bayii, o ti pada si sukuu, to si je pe Ploi Ibadan (The Ibadan Polytechnic) lo wa.
O ni odun meji si asiko ti a wa yii ni oun yoo fi ere sise sile, tori oun fe se awon nnkan miiran.
Igba naa ni yoo pe aadota odun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…