Home Orisirisi ‘Arun ogbe inu (ulcer) lo mu Ogogo nigba ti ara re ko ya’
Orisirisi - July 1, 2018

‘Arun ogbe inu (ulcer) lo mu Ogogo nigba ti ara re ko ya’

Okan lara awon omo ti Olorun fi jinki agba onifiimu, Hassan Taiwo, ti araye mo si Ogogo, ti so opo nnkan ti awon eniyan ko mo nipa osere naa.
Omobinrin naa ti oruko re n je Olawunmi ni nigba kan ti aare nla se baba oun, wahala nla ni molebi awon la koja.
O ni nigba naa, opo eniyan lo so isokuso lori aisan to se Ogogo.
O ni oun ti won ko mo ni pe arun ogbe inu ati ohun to maa n di sinu eniyan bi okuta, iyen appendix, lo mu u.
Lara awon nnkan miiran to tun so, o ni baba oun kii se ofale oloju-ko-mu-o-lo rara.
Arabinrin naa se alaye pe bi o tile je pe opolopo obinrin lo feran lati sunmo baba oun, nitori pe gbajumo osere ni, o mo bo se maa n ko ara re nijanu, ti kii sii maa n yan won lale kaakiri.
Olawunmi so ninu iforowanilenuwo pataki kan pe iyawo meji pere ni baba oun ni, to si je pe omo bii marun-un lo bi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…