Home Orisirisi Tanka to gbina fa iku oro ati ofo dukia ni Lagos-Ibadan Expressway
Orisirisi - June 28, 2018

Tanka to gbina fa iku oro ati ofo dukia ni Lagos-Ibadan Expressway

0018e361-b506-4905-aabe-c4a3a04b0b6b

Tanka kan to gbina ni irole oni ni agbegbe Otedola Bridge, ni eti Berger, ni Lagos-Ibadan Expressway, ti fa iku gbigbona fun opo eniyan.
Opolopo moto lo jonna guagua, ti awon eniyan kan si jona mo inu won.
Ajalu naa sele nigba ti moto ajagbe ejo naa yi danu pelu epo betiro ninu re.
Bayii ni o se lana, ti gbogbo awon moto to tele e leyin si n gbina.
Igbe ‘Oro’ lo gba enu opo eniyan, paapaa awon ti ina mo mo moto.
Ijoba Ipinle Eko ati awon alaabo gbogbo si n ja fitafita lati dawo wahala naa duro, sugbon nnkan ti baje pupo.
Laasigbo naa mu ki ona di patapata, ti moto wa to lo rere titi de Third Mainland Bridge, ni nnkan bii meeli mewaa si ibi to ti sele.
Iberu wa n mu ki onikaluku to ni eniyan loju ona ma ape won yajoyajo, ki Olorun ma je ki a se konge aburu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…