Home Orisirisi Amerika sọ̀kò ọmọ Nàìjíríà mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n sílé
Orisirisi - June 21, 2018

Amerika sọ̀kò ọmọ Nàìjíríà mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n sílé

Orileede Amerika ti fi omo orileede Naijiria merinlelogbon ranse si ilu Naijiria. Esun ti won fi kan won lo ni orisiirisii, won ni egboogi oloro ni o sakoba fun awon kan nigba ti awon kan ko ni iwe ti won fi wole, bii ki won lo ori olori, orukooloruko ati bee bee lo ni won se.
Okunrin mejilelogbon pelu obinrin meji ni won fi ranse. Akoba to wa ninu ifiranse pajawiri yii ni pe, ijoba ilu Amerika ko ni je ki won mu eru kankan wa sile. Aso to ba wa lorun won ti asiri asise tabi iwa odaran won ba fi lu si owo awon agbofinrin ilu naa.
Awon alase eto egboogi ni Naijiria (NDLEA) ati awon alase papako oko ofurufu ni won tewo gba won ni papako ofurufu ti Ikeja.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…