Home Orisirisi Abba Kyari: Ogbontarigi olopaa to n segun awon ogbologbo odaran
Orisirisi - June 7, 2018

Abba Kyari: Ogbontarigi olopaa to n segun awon ogbologbo odaran

download
Oun lo mu awon ole to ja ni Offa
Oun lo mu Evans ajinigbe
Oun lo mu Godogodo, China, Nnamdi, Yemi Boss, Abdullahi, Victor ati Vampire
Se oogun lo n lo ni abi ogbon ori?

Mudasir Alabi
Ogbontarigi olopa kan n be nile yi, e je a wi
Oun nii t’owo odaran bomii gbona
Oun nii so pe ki keke o pare mo asebi lenu
Bi ole ba n fo fere, to n fo’ganna
To wa n tori iroko be sori ile
E ba mi wi fun un pe ko rora se
Idi ni pe ojo to ba f’oju kan Kyari ro woo…

Opo eniyan ni enu si n ya lori awon aseyori nla nla ti ogbologbo olopaa ti a mo si Abba Kyari n se ni Naijiria o.
Lati igba ti won ti da ile ise olopaa Naijiria sile, boya ni a tii ri iru ti Abba Kyari ri.
Eni odun bii merinlelogoji (44 years) ni, sugbon o ti se aseyori ti olopaa to je aadorin odun ko tii se.
Bee, odun 2000 lo darapo mo ile ise olopaa ile wa.
Ti ajalu odaran kan ba ti ba awon olopaa, ti won ta a ti ko ba a, ti o da jinnijinni sile nile loko, Abba Kyari ni oga olopaa maa n so pe ki o yanju re.
Bee, okunrin naa kii sii ba a ti. Idi niyi to fi je pe oun ni esu leyin ibeji awon ogbologbo odaran bii ole, apaayan ati ajinigbe to buru julo.
Ki a maa ba opo lo sile oloro, aseyori to sun mo etile julo ni bi Abba Kyari se ko awon otelemuye sodi, ti won si se awari awon karanbaani adigunjale ti won ja ni ilu Offa ni nnkan bii osu meji seyin.
Bi awon ole naa se gbe ogun jade, ti won n pa niwa, ti won n pa leyin, ti won n pa ara ilu, ti won n pa olopaa, ti won n pa olomoge ti won si n pa aboyun, ko si eni to ro pe laarin osu kan, owo sinkun awon olopaa le te won.
Sugbon nigba ti Oga Olopaa yan Abba Kyari pe ki o ko awon iganniko olopaa miiran s’odi, awon ti won mo Kyari bi eni m’owo so pe oun naa ni apa re ka a.
Sugbon awon ti won ri bi awon odaran naa se huwa so pe Olorun nikan lo le mu won.
Ki a to wi, ki a to fo, Abba Kyari ti fakoyo, o ti f’oju awon odaran naa han.
Ose to lo ni won tun gba meji ninu awon olori won to salo mu!
Ni ti oro Kyari, omo tuntun kii se akopa aje. Oun naa lo se bebe nigba ti o gba oba awon ajinigbe, Evans, ni ilu Eko.
Leyin pe Evans buru bii elegun Sango, to le ji, to le pa, o tun je eni to gbon bii asarun. Ogbon ewe re ju ti ijapa lo.
Eyi lo fa a to fi je pe bi o ti je ogbologbo odaran to, aarin awon olowo lo kole si ni Magodo, lebaa Ojodu Berger, ti won jo n je, ti won jo n mu.
Won o n se ipade bi ilu yoo se toro, won jo n sanwo sikioriti, won si jo n se ararindin.
Sugbon inu ile alarinrin ti o n gbe, ile Esu Laalu ogiri oko ni, mewaa n lo nibe.
Nigba ti ojo ifura ro laarin awon olopaa, Abba Kyari naa ni won gbe ise naa fun, pelu awon eni bii eni, eniyan bi eniyan ninu ise olopaa.
Ki a ma deena p’enu, Abba Kyari gbe Evans bi iwo se n gbe eja. Atigba naa ni Evans ti wa ni takute olopaa, ti o si di eni ti won n fi seeni mu lo si ile ejo.
Nigba ti Ipinle Eko gbona janjan laye Fashola, Abba Kyari naa lo se ise akoni. Awon odaran ti eni kankan ko lee sun mo, awon jaguda ti won le ju Anini ati Isola Folorunsho lo, oun naa ni o maa n gba ina oju won.
Idi niyii to fi je pe ko si ohun ti Fashola ko se nigba naa, ki awon Abuja ma fi le gbe Kyari kuro ni Eko.
Lara awon agbako odaran ti Kyari ti gbamu ni Abiodun Ogunjobi, ti alaje re n je Godogodo, China, Nnamdi, Yemi Boss, Abdullahi, Victor ati Vampire.
Ile Yoruba nikan ko ni irawo Kyari ti tan. Oun naa lo mu ogbologbo odaran ti oruko re n je Ndagi’ ti inagije tie n je Spirit, Itumo Spirit ni emi ti a ko ri. Sugbon nigba ti esu ti okunrin naa de iwaju Kyari, Kyari ri i, gege bi oruko omo ti n ro’mo.
Awon aseyori alailegbe yii lo fa a ti awon kan fi n ro pe boya oogun ni akoni agbofinro naa n ro ni. Won ni boya o ni onmo, to n je ko mo ohun ti elomiran ko mo. Awon kan ni boya agbero lo lo fun awon awon jaguda paali, ti awon kan si ni boya afeeri wa ninu eje re ni.
Sugbon nigba ti oga awon onise isoni (security) kan ba IROYIN OWURO soro, o ni oro Abba Kyari ju oogun lo. O ni ti a ba wa idi re daadaa, o je eni kan ti Olorun wa leyin re. O ni bee, Olorun fun un ni ebun ati opolo ninu ise otelemuye.
Alagba naa, ti oruko re n je Bernard Uche, so pe, “A tun ni lati mo pe Abba Kyari ni ife Naijiria lokan. O n sise tokantokan. O tun ti ni i lokan pe oun le ja ajasegun lori ise yowu ti won bag be fun un; eyi lo tun maa n je ko ni aseyori.”
Ohun kan to tun wa je iyalenu ni pe eko imo agbegbe (Geography) ni Abba Kyari ko ni Ifafiti Maidiguri, iyen University of Maiduguri. Omo Maiduguri naa si ni; ibe n won bi isi. Sibesibe, o n se ise agbayanu ti awon to ko imo nipa odaran, iyen Criminology, k ki won to di olopaa ko lee se.
O kare lae, Abba Kyari, Asikari to moye gidigidi.
Adura IROYIN OWURO nip e ki Olorun maa fun Abba Kyari se, ki awon odaran naa si ronu piwada, tori Asikari to moye ti fee de.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…