Home LÁGBO ÀRÍYÁ Fela lo ni ki n maa fi Pidgin sinu orin mi – Shina Peters
LÁGBO ÀRÍYÁ - June 3, 2018

Fela lo ni ki n maa fi Pidgin sinu orin mi – Shina Peters

.Oludasile afro juju di eni ogota odun
Ilu Eko yoo mi titi lojo Alaaruba to n bo yii, nigba ti akorin pataki Sir Shina Peters, yoo di eni ogota odun – 60 years.
Opo osere ati awon eeyan jankan-jankan miiran lo ti n mura sile lati ba akorin ti a mo si SSP seye.
Lara won ni King Sunny Ade, Ebenezer Obey, Wasiu Ayinde, Adewale Ayuba, Mega 99 ati Dele Taiwo.
Shina Peters so pe oun dupe pupo lowo Olorun bi o se da emi oun si, ti o si je ki ise owo oun parun.
Nitori idi eyi, o ti fe da ajo kan sile bayii, ti won pe ni Shina Peters Foundation, ti yoo maa ran awon olorin to ba sese n dagba soke lowo.
Ninu arojinle to se SSP ni eni kan pataki ti Olorun fi se sababi fun oun ni Fela Anikulapo Kuti. Gege bi o se so, o ni oun lo fun oun ni imoran meji kan, to si je pe imoran naa sise fun oun gidi.
Ekinni ni pe o ni, nigba ti oun lo ba a pe ki o gba oun nimoran, Fela so pe ki oun wa iru orin kan to le ba ohun (voice) oun mu, tori oun naa dab ii ti koko. Fela ni iru oun bee ni oun naa ni, ti oun si fi nko iru orin ti oun n ko.
Ni idakeji, Fela so fun Shina Peters pe ki o ri i pe oun n fie de adalu PIDGIN sinu orin oun, tori opo eniyan ni ko gboyinbo.
Ti a ba wa wo aseyori ti Shina Peters ni ninu orin re, a o ri i pe o gba imoran ti Fela fun un, se ori eni nii gbe alawo rere koni. Bee, ka soro fun ni ka gbo ni iyi omo eniyan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…