Home Orisirisi Nje Fayemi le gba Ekiti mo Fayose lowo?
Orisirisi - May 26, 2018

Nje Fayemi le gba Ekiti mo Fayose lowo?

PDP ni ogun yoo ja bi APC ba seru ibo
Buhari ni PDP se magomago ni 2014

Titi ti osu keje odun yoo fi de, nigba ti ibo gomina yoo waye ni Ipinle Ekiti, o jo pe bata awuyewuye yoo si maa ro ponlaponla ni o.
Idi ni pe awon egbe oselu mejeeji ti won fe jo na a tan bi owo, iyen APC ati PDP, jo mo ara won bi eni mo owo ni. Ekinni mo eyi ti ekeji le se, ekeji naa si mo ohun ti ekinni ti se ri.
Bi ologbon meji ba wa n fi obe osiki je iyan, omo tooro lo maa n ku lawo leyin o reyin.
Mewaa sele ko to di pe Dokita Kayode Fayemi di oludije fun APC. Awon oludije bii ogbon lo dide, ti Alaba Segun Oni ati Babafemi Ojudu wa lara won. Arugudu to koko sele laarin won fa ki won tun ibo naa di, sugbon ti Fayemi si jawe olubori.
Ni ti PDP, igbakeji Gomina Ayodele Fayose, Ojogbon Kolapo Olusola, ni Ifa mu nigba ti awon naa se idibo tiwon.
Ohun to wa sele ni pe egbe oselu mejeeji ni ikunsinu wa lori yiyan awon oludije mejeeji. Bi ikunsinu yii yoo se ri lasiko ibo gan-an, eni kan ko tii mo.
Lara awon ti won si n binu lori bi Fayemi se bori ni Segun Oni. Koda, awon kan ni oun yoo fi egbe sile, sugbon oti so pe bi a ba n jab ii ka ku ko, oun ko fi APC sile.
Ni pataki julo, bibori Fayemi mu awon akiyesi kan wa ninu oselu APC. Lona kinni, awon onwoye kan so pe o tumo si pe Aare Muhammadu Buhari tun fe yege ni Ekiti bo se yege ni Ondo, lori bi Alagba Rotimi Akeredolu se jawe olubori.
Won ni eyinju Buhari ni awon mejeeji.
Nipa bayii, won fi kun un pe o tumo si pe Asiwaju Bola Tinubu tun ti fe padanu sise adari ipinle miiran ni ile Yoruba. Idi ni pe won gba pe aarin Tinubu ati Fayemi ko gun. Nigba ti oro wa ri bayii, ki ni ki Tinubu se lori Fayemi?
O jo pe o so sini lenu, o buyo si i tori ko ni fe ki PDP gba Ekiti mo awn lowo leekan sii. Ana wa be ise, iku be owe, bi a ko ba je ise iku, yoo pani; bi a ko si se owe ana, yoo gba omo re.
Ko pari sibe. Egbe PDP si n ke rara pe o seese ki APC fe se eru ibo. Gomina Fayose ti so bee; bee naa ni Alaga egbe naa, Alagba Uche Secondus.
O so funawon oniroyin pe eni to ba o oju APC ko tete so fun un pe ko gbodo dabaa sise eru ibo. O ni bi o bad an an wo, yoo dan an an, to si le fa opin de ba Naijiria.
Oro idibo Ekiti je elege gbaa. Awon eniyan ibe ko fe iyanje. Sibesibe, awon omoran so pe ko si egbe oselu kankan ti kii se eru ibo ni Naijiria. Won ni ona ti won fi n se e lo yato.
Won ranti pe ninu ibo to gbe Fayose si ipo, awon APC naa kefin pe magomago wa nibe. Won ni balubalu ni t’afin kun bi awon omo Ekiti se dide gbaruku ti Fayose.
Won ko sai ranti bi won ni won se gbe owo ribiribi wole ni ibo ku si dede, lara eyi to di oaran si Minisita fun Oro Aabo tele, Musiliu Obanikoro, lorun. Hmmm, Obanikoro ohun ti wa ni APC bayii!
Nigba ti o n gba awon olori APC ni ile Yoruba lalejo lojo Jimoo, Aare Muhammadu Buhari naa so pe magomago wa ninu idibo gomina ni Ipinle Ekiti ni 2014.
O ni PDP se magomago, leyii to je pe eyi lo mu ki Fayose wole.
O ni awon omo egbe APC ko gbodo faaye sile fun eyi mo.
O ni ki won fowo sowo po, ki won sig be Fayemi de ebute ogo.
O ni gbogbo nnkan daadaa, to fi mo iwa omoluabi, akikanju ati oloooto, ti oun mo mo awon Ekiti tele ni ko si nibe mo latigba ti PDP ti gbajoba nibe.
Bi Aare ko tie daruko Fayose, eni to je alatako re gidi, opo eniyan ti mo ibi to n soro lo.
Ni pataki, awon onimo ijinle n fe ki egbe oselu mejeeji se jeje, ki won je ki ipinnu ara ilu di mimuse.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…