Home Orisirisi Iku Aisha Abimbola si n ko opo eniyan ni ‘Haa!’
Orisirisi - May 26, 2018

Iku Aisha Abimbola si n ko opo eniyan ni ‘Haa!’

Aisha-Abimbola-1aisha abimbola burial pictures
Omoge Campus ku leyin odun kan geere ti Moji Olaiya di oloogbe
Canada ni awon mejeeji ku si
Ayo Adesanya, Odunlade Adekola, Saidi Balogun, Kabirah Kafidipe, Toyin Aimakku, Eniola Badmus sedaro

Eeru fun eeru, eepe fun eepe, iku tun da ibanuje nla sile laarin awon osere fiimu Yoruba lose to lo, nigba ti Aisha Abimbola di oloogbe.
Orle-ede Canada ni Aisha, ti opo eniyan mo si Omoge Campus, ku si, leyin to ti ja ijakadi pelu arun kansa to mu u ni oyan, iyen breast cancer.
Aisha naa gbiyanju die, sugbon aruun jejere naa je eyi to buru jae. Bi o se maa n pa okunrin lo n pa obinrin, ti ko si da olowo mo yato si talika.
Bi a ko ba gbagbe, arun naa lo pa Aare Musulumi ni ile Yoruba, Alhaji Azeez Arisekola Alao. Arun naa lo pa iyawo Ogagun Ibrahim Babangida, iyen, Maryam Babangida.
Bee, arun naa lo pa Ojogbon Dorah Akunyili, to je adari ajo NAFDAC tele.
Awon omoran naa ranti pe arun naa lo gbe okan lara awon oludasile banki Guranty Trust Bank, Ogbeni Tayo Aderinokun, lo.
Idi niyi ti opo eniyan fi maa n se adura ki Olorun ma je ki won ko agbako arun cancer; bee ni awon dokita naa maa n ke pe ki kaluku kiye sara, ki won si tete sare lo si osibitu ti won ba kefin ohun to le di kansa.
Iroyin fi ye wa pe iru igbiyanju bee lo fa a ti ti Aisha naa se tara sasa lo si Canada. Sugbon iku ti yoo pani, ko ni sai pani.
Nigba ti awon elegbe Aisha ni idi fiimu, ati opo lara awon ololufe re gbo nipa iku re, o ya won lenu gidi ni.
Idi ni pe won ko mo nigba to wa lori aare.
Lara awon tie nu ya ni Ayo Adesanya ati Eniola Badmus.
Bee naa ni Kabirah Kafidipe ti a mo si Arapa re gangan ati Toyin Aimakhu ti o n je Toyin Abrahams bayii.
Awon osere bii Kunle Afod, Afeez Owo, Odunlade Adekola, ati Emmanuel Adejumo naa ke para nigba ti won gbo nipe iku Aisha ni.
Won ko mo pe o ti wa lori idagunle aisan tele.
Eni kan to jo pe o mo die nipa aisan naa ni Lola Alao. Ninu oro kan to so, o ni oloogbe naa je eni kan ti kii fe maa f gbe gbogbo oro re le araye lowo.
O ni idi niyi ti ko fi pariwo sita nigba ti wahala cancer de.
Lola Alao naa lo se ikilo pe eni kankan ko gbodo fun awon kan ti won fe maa se itoro owo lori atigbe oku Aisha wale lati Canada.
Osere naa ni enikeni to ba so bee, iro ni won n pa. O ni omo Canada ni Aisha je, leyii to tumo si pe o ni iwe ase lati maa je anfaani ti gbogbo omo Canada n je, eyi ti awon oyinbo n pe ni citizenship.
Ohun ti Lola Alao so di otito nigba ti Saidi Balogun kede pe ojo Alamisi to lo ni won yoo sin Aisha Abimbola si Canada, to si je pe bee na ni o ri.
Awon molebi re lo wa nibi isinku naa, ti won si te aso ayesi ti keu wa lara re le ori posi r. Idi nip e elesin Musulumi ni Aisha nigba aye re; ilana esin Islam naa ni won si fi sin in.
Eyi yato gedegede si ohun to sele ni odun to koja nigba ti osere Yoruba miiran, Moji Olaiya, di oloogbe.
Ore ni Moji ati Aisha je nigba aye won. Eyi lo je ki o ya awon eniyan kan lenu pe leyin bii odun kan geerege ti Moji di oloogbe naa ni Aisha naa lo je Olorun nipe.
Bee, Canada naa ni awon mejeeji ku si. Sugbon sa o, arun cancer ko lo pa Moji, leyin to bimo tan ni olojo de.
Ni pataki, awon eniyan to fi oro mo Olorun lokan so pe amuwa Olorun ni isele mejeeji, ati pe kadara a lau; bi Edumare se fe lo maa n se ola re.
Bakan naa, a o ni gbagbe pe won gbe oku Moji pada si Naijiria ni, to si je pe Asiaju Bola Tinubu lo gbe owo ti won fig be e wa si Eko sile.
Eni kan to tun jo pe o gbo nigba ti aisan n se Aisha ni apanilerin ti a mo si Ali Baba.
O so pe lojo kan ti awon n soro lori ero alagbeka whatsapp, Aisha so pe ailera kan n se oun. Sugbon ko so hulehule re.
Ninu oro ti opo akegbe Aisha so, won ni o je eni kan ti iwa re dara pupo. Won ni kii fi ise sere. Bee ko gba igbakugba.
Bi apeere, Kabirah ranti ranti bi oloogbe naa se kopa ninu fiimu re ti o (iyen Kabirah) pe akole re ni Malaika. O ni o huwa bi eni ti inu re maa n dun si nnkan elomiran, ti o si ni ebun to giriki nipa ise fiimu.
Oun ati awon eniyan to ku wa gbadura ki Olorun te Aisha Abimbola si afefe rere.
Ilu Eko aromisa legbelegbe ni won bi arabinrin naa si ni nnkan bii odun merindinlaadota (46 years) seyin.
O se igbeyawo, to si bi omo meji si ile oko, ki igbeyawo naa to daru.
Nje ki Olorun te Aisha Abimbola si afefe rere.
Iku re tun muni ranti iku awon gbajumo osere Yoruba to di oloogbe ni kope-kope yii, paapaa awon to je obinrin. Lara won ni Herieta Kosoko, Toyin Majekodunmi (Iya Kike), Mulikat Adegbola (Ashabi Iya Adini) ati Modupe Oyekunle.
Bee naa ni Alagba Adebayo Faleti, Adesina Adesanya ti a mo si Wolii Ajidara, Ojogbon Akinwumi Isola, Olumide Bakare ati Baba Sabiko

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…