Home Orisirisi Toyin Aimakhu n mura igbeyawo pelu agbejoro
Orisirisi - May 21, 2018

Toyin Aimakhu n mura igbeyawo pelu agbejoro

IMG_7895-1Seun-Egbegbe-Playground
Iroyin ayo n sele lowo lagbo osere fiimu ti a mo si Toyin Aimakhu o, ti o ti yi oruko ara repada si Toyin Abraham.
Leyin ti o ti amubo kan tabi meji lagbo awon okunrin oloju ko-mu-o-lo, o jo pe Olorun ti gbe eni tie naa ko o.
Toyin ati arakunrin kan ti won pe ni Seun Egbegbe ti ko jo maa n se wolewode tele ki atuka to de.
Okunrin naa tile wa ni panpe olopaa bayii latari esun ole ti won fi kan.
Okunrin kan to je osere fiimu ni Toyin tun jo se afori-aforun, sugbon ti nnkan ko senu rere. Okunrin naa, Adeniyi Johnson, se igbeyawo pelu obinrin miiran laipe yii.
Sugbon niwon igba to jo pe eledaa Toyin naa ko sun, o ti di eni to gba oruka igbeyawo ku-dede, iyen engagement ring.
O fi oruka naa han awon ololufe re lori ero alatagba, ti erin si pa eeke tie naa.
A gbo pe agbejoro kan lo wa nidi oro naa, bi o tile je pe won ko tii darukore, ti won ko si tii gbe foto re jade.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…