Home Orisirisi Ronaldo ati Salah: Sooso meji fe foju kan ara won. Liverpool le Roma jade
Orisirisi - May 2, 2018

Ronaldo ati Salah: Sooso meji fe foju kan ara won. Liverpool le Roma jade

Gudugbe yo ja nibi asekagba ti Champions League ti odun yii, nigba ti Real Madrid ati Liverpool yoo figa gbaga.
Liverpool jawe olubori ni asaale oni, nigba to le Roma jade.
Bi o tile je pe Roma ni ami ayo merin, ti Liverpool ni meji nigba ti won pade ni Rome, Liverpool bori tori ami ayo marun-un si meji ni awon ni ni England lose to lo.
Nigba ti Real Madrid ati Liverpool ba pade ni final, awon agbaboolu meji ni oju yoo wa lara won ju. Awon naa ni Ronaldo ati Salah.
Nigba ti Ronaldo ti gba Champions League pelu Real Madrid leemeta, Salah ko tii gba okankan pelu Liverpool.
Nigba ti Ronaldo je asiwaju laarin agbaboolu agbaye bayii, Salah ni irawo re si n tan ju lowolowo yii.
Ohun ti yoo wa sele lojo ti sooso meji ba fi oju kan ara won ni a ko tii mo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Nàìjíríà sì nílò Ọbásanjọ́ fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí- Buhari

Nàìjíríà sì nílò Ọbásanjọ́ fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí- Buhari Fẹ́…