Home Orisirisi Buhari so ede oyinbo to dan moran ni Amerika
Orisirisi - May 1, 2018

Buhari so ede oyinbo to dan moran ni Amerika

Aare Muhammadu Buhari fakoyo ni orile-ede Amerika lanaa, nigba ti Olori Orile-ede naa, Ogbeni Donald Trump, gba a lalejo ni ile ijoba won ni Washington.
Opo eniyan ni eru ti n ba tele pe Buhari le ma soro ja geere nigba ti oun Trump ba pade, paapaa nigba to je pe Trump je eni an to je aseyiowu-u eniyan.
Sugbon nigba ti Buhari ka iwe apileko oro to ba Trump so, o se ise akoni. Oro re ja geere, ko si awon oro naa pe, ko wuko, bee ni ko fi okan pe meji.
Leyin eyi ni oun ati Trump bu ow lu iwe awon ajosepo kan laarin Amerika ati Naijiria.
Opo awon ti ko feran Buhari ni won ti n so o lowo, so o lese, ti won n wo enu re fetofeto, tori won ro pe ede oyinbo ko ni ja gaara lenu re ni.
Won tun ro pe Trump le maa ba a leru. Sugbon oun naa fi han won pe okete kan ko ga ju okan lo, afi eyi to ba gori ebe.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…