Orisirisi - April 24, 2018

A ko le ri iru Arsene Wenger mo – Alex Ferguson

…ifeyinti Wenger si n mi papa isere titi
Akinwale Taophic.
E gbo na, kin ni awon ololufe re boolu fe ki Arsene Wenger o se gan-an? Kin ni won tun n fe ki ole o se na? Won ni ko gbe tow re sile, o gbe t’owo re sile?
Lati nnkan bii odun merin seyin ti ifaseyin ti n ba egbe Arsenal ni opo eniyan ti n bu Wenger. Won ni o ti dagba, o ti gbo, won ni ko maa lo.
Won bu u titi, won pee ni Baba Ijebu; won ni ahun ni, kii fe fi owo to joju ra agbaboolu. Eyi o wu a wi, adari agbaboolu naa to je omo orile-ede Faranse se bi okunrin lose to lo. Ko sigba wo, bee ni ko gbe oogun je. Sugbon o ya opo eniyan lenu nipa fifun awon alase Arsenal ni iwe pe, o to gee. Alubata kii darin. Oda Arsenal won pada fun won.
Sibesibe, awon eniyan kan si n suti ete si Arsenal ati awon omo egbe Arsenal.
Lati odun 1196 ni Wenger ti n dari Arsenal,ti o si gba awon ife eye kan fun won.
Ewe, die lara awon to sise po pelu Wenger ni won ti n yombo re. Lara won ni Nwakwo Kanu, to kan saara si Wenger gege bii eni ti ori re pe, to si je koosi to maa n mu idagabsoke bas awon agbaboolu.

******
Yoruba bo won in ko si oun ti o ni ibere ti ko ni opin laye! Akoni ni oju ija, ti o je ogbontagiri larin awon olukoni egbe agbaboolu lagbaye ajaaja ni orileede England, Arsene Wenger, ti ko iwe fi ipo re sile, eyi ti yio wa si imuse lati ipari saa ti a wayi.
Ikowe fi ipo sile yi waye ni ale ojo Alamisi, ojo kokandinlogun osu kerin ti a wayi, ni igba Arsene Wenger eni odun mejidinladorin (68years) pe apejo awon oniroyin leyin igba ti o ti fun awon Igbimo ti won n se akoso egbe agbaboolu Arsenal ni iwe tan, o si so ero okan re lati kuro ni inu iko naa sugbon ko so boya oun maa fi eyin ti kuro ni inu ise olukoni ere boolu alafesegba ni tabi oun maa lo si inu egbe agbaboolu miran lati te si iwaju.

Se Yoruba lo tun wo ti i ti ti won so wi pe oju ti ore re o so pe oju ko ti e, won ni ojuti ni iru eniyan bee ko ni, eyi ni o fa a ti opolopo awon olukoni kaakiri agbanla aye fi n so ero okan won ni ori ikowe fi ipo sile akoni naa. Awon olukoni ti won je gbogi ninu awon ti o so oro lori isele ikowe fi ipo sile naa ni, olukoni egbe agbaboolu Chelsea ni igba kan ri, ti oun tu iko egbe agbaboolu Manchester United lowolowo bayi, José Morinho; olukoni egbe agbaboolu Chelsea lowolowo, Antonio Conte, sugbon eyi ti o ni ikimi ju ninu gbogbo re ni ti akoni nla, ti a le fi oro oun ati Arsene Wenger we ara won ni inu ise olukoni, ti o tun je wi pe a ko le so oro olukoni ere boolu alafesegba ni gbogbo agbanla aye ki a ma da oruko re, ti oun naa tun wa lara olukoni ti o lo saa ti o pe ju ni inu egbe agbaboolu kan soso, ti o je olukoni fun egbe agbaboolu Manchester United fun odun merindinlogbon (26years), ti o si fi eyin ti si inu iko naa, Sir Alex Ferguson.
Ni igba ti baba Ferguson n so oro lori ikowe fi ipo sile Wenger, o so wipe, “Mo ni ibowo ti o po fun Arsene Wenger ati fun ise ribiribi ti o se ni inu egbe agbaboolu Arsenal, ati wi pe ki i se nkan ti o rorun rara lati fi odun mejilelogun (22years) igbesi aye eniyan se ise ti eniyan ni ife lopolopo si fun egbe agbaboolu kan soso, ajaja ni iru akoko yi ti o je wi pe agidi ni awon olukoni fi n lo saa kan tabi meji ki won o to gba ise lowo won ni inu egbe agbaboolu. Eleyi fi han wipe aseyori nla ni Wenger se ni inu egbe agbaboolu ti o tobi bi ti Arsenal lati wa ni ibe pe to iye odun yen. Inu mi dun lati gbo w ipe o ko iwe lati kuro paapaa ni iru akoko bayii ti gbogbo awon iko alamojuto egbe agbaboolu naa le fun ni eye ati iyi ti o to si gege ni akoni nla ti o ti se gudugudu meje ati yaaya mefa fun won. Nitori wi pe lai si iyan rara, Arsene Wenger je okan lara olukoni ti o se aseyori julo ni inu liigi ile Geesi bee si ni inu mi dun gidi gan pe mo je okan lara awon olufi igagbaga pelu e, alajo se ise po ati ore si iru eniyan nla bee. Fun idi eyi, ti mo ba so wi pe ko le si iru Arsene Wenger mo, mi o so oro ju nitori wi pe ki a to le ri olukoni ti yoo ni suuru ati ifarada pe to iye odun ti o (Wenger) lo ni inu egbe agbaboolu kan, ile yoo ta sii, tabi ki a ma ri iru e mo.”

Baba Ferguson wa gba ni adura fun Wenger wipe ki o mo eyin ikowe fi ipo sile naa si rere.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…