Home Orisirisi Ina jo dori koko, janduku ji opa ase ile igbimo asofin agba losan gangan
Orisirisi - April 19, 2018

Ina jo dori koko, janduku ji opa ase ile igbimo asofin agba losan gangan

Senato Ben Bruce to n soju ipinle Bayelsa lo n salaye nile igbimo asofin agba pe ijongbon n rugbo bo ni orileede yi. O ni oun ko deru ba enikankan sugbon a ko gbodo maa dibon bi eni pe ko si isoro kankan ni ilu yii. O ni ebi n pa awon eniyan ni ilu, ko si ise bee si ni awon eniyan n ku lojoojumo. O ni ti awon ti awon wa ni ipo olori ba ko lati gbe igbese to lagbara to si gbodo ya kiakia, ti ijongbon ba be sile, o le seese ki agbara ma kaa mo.
“Erin ko yato to fi de ilu Oyinbo ni oro Seneto Adeola Olamilekan to wa lati ipinle Eko, oun tile ni ki ijoba apapo da gbogbo awon olori ologun duro ti won ba ko lati kowe fi ise sile. O ni ojoojumo ni a n padanu emi ni orileede yii. O ni “akuku joye san ju enu mi ko ka ilu lo”. O ni, ni oju ti oun, gbogbo awon oori ologun lo ti lo gbogbo ogbon ati agbara ti won ni ti ko si so eso rere ni orileede yii. O daa laba ki won lo wa ise miran.
Ojo keji tii se ojo weside ni ina jo dori koko, ti awon janduku ya wo ile igbimo asofin agba naa, won gbe opa ase, won gbe seneto kan, won si tun se awon eniyan kan lese. Aje ke lana, omo ku lonii ni oro naa jo.
Awon kan funra si seneto to wa lati ipinle Delta, Ovie Omo Agege, awon olopaa gbee ni ojo weside naa, won si tun fi sile ni igbeyin. Iwadii to gbopon si tun n lo lowo bayii lati fi owo sinkun ofun mu awon odaran naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…