Home iroyin Ijo Shiite yari, awon olopaa ko jale l’Abuja
iroyin - April 19, 2018

Ijo Shiite yari, awon olopaa ko jale l’Abuja

Awon ijo elesin musulumi ti won fi ile Hausa se ibujokoo ti gbogbo eniyan mo si ijo SHIITE ni iwode won pe ojo keji lonii ojo isegun ni ilu Abuja. Awon ijo yii n se iwode lori olori ijo won ti o ni ede aiyede pelu awon ologun ni nnkan bii odun meji seyin, ti ijoba si fi owo sinkun ofin gbee si atimole. Olori ijo naa ni EL-ZAKZAKY, awon ijo yii ni iyanje nla ni eyi ni igba ti ile-ejo ti ni ki ijoba fi oga awon sile.
Awon olopaa ni ko si aaye fun iwode kankan lasiko yii. Eyi mu ki won gbena wo oju ara won. Awon olopaa ti fi owo sinkun ofin mu eniyan marundinlogofa ni ana, sibe iwode tun waye ni oni, ni eyi to tun mu ki awon olopaa maa yin taju-taju si oke ki awon eniyan yii ba le pada sile won.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…