Home iroyin PDP ko tii mo ohun to fe se lori Atiku
iroyin - March 28, 2018

PDP ko tii mo ohun to fe se lori Atiku

Bi ologbon se n desa ni omoran n de ni oro egbe Peoples Democratic Party ati Igbakeji Aare Orile-Ede yii tele, Alhaji Atiku Abubakar, je o, lori erongba Atiku lati du ipo aare ni odun to n bo.
Odun to lo ni Atiku binu kuro ni APC, to si pada si PDP to ti wa.
Ohun ti opo eniyan koko ro ni pe bi Atiku se de PDP ni won yoo yan an laayo gege bii oludije won. Sugbon oro ko tii ri bee.
A gbo pe awon kan ti won ti ni I lokan lati du ipo, gege bii Alhaji Lamido ko setan lati gba.
Bakan naa, awon oloye egbe n wo ajaga to wa lorun Atiku, to fi mo iha ti Oloye Olusegun Obasanjo ko si i.
Okan lara awon oloye egbe naa to ba IROYIN OWURO soro, sugbon ti ko fe ki a daruko oun, so pe awon n wa eni kan ti ojo ori re ko lo soke ju, ti yoo sit un je itewogba kaakiri Naijiria.
Amo o, oro oloselu kii pe yi. Idi niyi ti awon kan fi ro pe PDP si le ko eebi re je nipa fifa Atiku sile.
Bi won ko tie ro nnkan miiran, won mo pe Atiku ni egbo kaakiri, latari egbe PDM re to ti wa lati ojo to pe. Bakan naa,won mo pe o ri jaje yato si pako.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…