Home Orisirisi Esun ile mejila l’Abuja: Adebayo Shitu n ba Oluwadamilare fa surutu
Orisirisi - March 28, 2018

Esun ile mejila l’Abuja: Adebayo Shitu n ba Oluwadamilare fa surutu

dare
Roforofo kan to be sile laarin Minisita fun oro Ibanisoro, Alhaji Adebayo Shittu, ati okan lara awon olubasise re tele, Ogbeni Victor Oluwadamilare si n jo bi ina papa ninu oye ni o.
Nigba ti Oluwadamilare ni Shittu je oun ni owo to to milionu merin naira, to je owo osu oun ni bii odun meta, minisita naa ni iro funfun balau ni, ati pe oun ti le okunrin naa to je abenugan lori iroyin, danu latari awon asemase kan.
Pabambari ibe ni pe Oluwadamilare fi esun ojelu kan Shittu.
O ni minisita naa ti ra ile bii mejila si Abuja. O ni o ti ra opolopo moto, to si je pe o sese ra ero itewe kan ni aadorun milionu naira o le meta ni – N93m.
Sugbn ninu esi Shittu ninu atejade kan, o ni iro nla ni Oluwadamilare n pa.
O wa so pe o gbodo setan lati lo toka si awon ile to ni oun ra ni Abuja, nigba ti awon adajo ba bi i leere.
Eyi tumo si pe o fe gbe okunrin naa lo sile ejo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara Orẹ Òtítọ́jù Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bí a ṣe ń pà…